Jeremiah 17:18 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí wọn ń ṣe inúnibíni mi, ṣugbọn kí ojú má tì mí. Jẹ́ kí ìpayà bá wọn, ṣugbọn má jẹ́ kí èmi páyà. Mú ọjọ́ ibi dé bá wọn; pa wọ́n run ní àpatúnpa.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jẹ ki oju ki o tì awọn ti o nṣe inunibini si mi, ṣugbọn má jẹ ki oju ki o tì mi: jẹ ki nwọn ki o dãmu, ṣugbọn máṣe jẹ ki emi ki o dãmu: mu ọjọ ibi wá sori wọn, ki o si fi iparun iṣẹpo meji pa wọn run.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jẹ́ kí ojú ti àwọn ẹni tí ń lépa mi, ṣùgbọ́n pa mí mọ́ kúrò nínú ìtìjú, jẹ́ kí wọn ó bẹ̀rù. Mú ọjọ́ ibi wá sórí wọn, fi ìparun ìlọ́po méjì pa wọ́n run.