Jeremiah 17:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ kò gbọdọ̀ ru ẹrù jáde ní ilé yín ní ọjọ́ ìsinmi. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan, ẹ níláti ya ọjọ́ ìsinmi sí mímọ́, bí mo ti pa á láṣẹ fún àwọn baba ńlá yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni ki ẹ má si ṣe gbe ẹrù jade kuro ninu ile nyin li ọjọ isimi, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe iṣẹkiṣẹ, ṣugbọn ki ẹ yà ọjọ isimi si mimọ́, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun awọn baba nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Má ṣe gbé ẹrù jáde kúrò nínú ilé yín, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ má ṣe ṣe isẹ́kísẹ́ ní ọjọ́ ìsinmi ṣùgbọ́n kí ẹ pa ọjọ́ ìsinmi mọ́ fún àwọn baba ńlá yín.