Jeremiah 17:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
àwọn ọba tí yóo máa gúnwà lórí ìtẹ́ Dafidi, yóo máa gba ẹnubodè ìlú yìí wọlé. Àwọn ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn ará Juda ati ará ìlú Jerusalẹmu yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọlé. Àwọn eniyan yóo sì máa gbé ìlú yìí títí ayé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni nwọn o wọ ẹnu-bode ilu yi, ani ọba, ati ijoye ti o joko lori itẹ Dafidi, awọn ti ngun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, awọn wọnyi pẹlu ijoye wọn, awọn ọkunrin Juda, ati olugbe Jerusalemu: nwọn o si ma gbe ilu yi lailai.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Ọba tí ó jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì yóò gba ti ẹnu-bodè wọlé pẹ̀lú àwọn ìjòyè rẹ̀. Àwọn àti ìjòyè wọn yóò gun ẹsin àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ wá, àwọn ọkùnrin Júdà àti àwọn olùgbé Jérúsálẹ́mù yóò tẹ̀lé wọn; ìlú yìí yóò sì di ibi gbígbé títí láéláé.