Jeremiah 17:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn eniyan yóo máa wá láti gbogbo ìlú Juda ati àwọn agbègbè Jerusalẹmu, láti ilẹ̀ Bẹnjamini ati pẹ̀tẹ́lẹ̀ Ṣefela, láti àwọn agbègbè olókè ati ilẹ̀ Nẹgẹbu, wọn yóo máa mú ẹbọ sísun ati ẹbọ ọrẹ wá, pẹlu ẹbọ ohun jíjẹ ati turari; wọn yóo máa mú ẹbọ ọpẹ́ wá sí ilé OLUWA.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn o si wá lati ilu Juda wọnni, ati lati àgbegbe Jerusalemu yikakiri, ati lati ilẹ Benjamini, lati pẹtẹlẹ, ati lati oke, ati lati gusu wá, nwọn o si mu ọrẹ-ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹran ati turari, ati awọn wọnyi ti o mu iyìn wá si ile Oluwa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ènìyàn yóò wá láti ìlú Júdà àti ní agbègbè Jérúsálẹ́mù, láti ilẹ̀ Bẹ́ńjámínì àti níbi òkè gúṣù láti orílẹ̀ èdè gíga. Wọn yóò wá pẹ̀lú ọrẹ ẹbọ sísun àti orẹ ọkà ẹran, ọrẹ ọpẹ́ tùràrí àti ìyìn wá sí ilé OLÚWA.