Jeremiah 17:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Yóo dàbí igi tí a gbìn sí ipa odò, tí ó ta gbòǹgbò kan ẹ̀bá odò. Ẹ̀rù kò ní bà á nígbà tí ẹ̀ẹ̀rùn bá dé, nítorí pé ewé rẹ̀ yóo máa tutù minimini. Kò ní páyà lákòókò ọ̀gbẹlẹ̀, nígbà gbogbo ni yóo sì máa so.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Yio si dabi igi ti a gbìn lẹba omi, ti o nà gbòngbo rẹ̀ lẹba odò, ti kì yio bẹ̀ru bi õru ba de, ṣugbọn ewe rẹ̀ yio tutu, kì yio si ni ijaya ni ọdun ọ̀dá, bẹ̃ni kì yio dẹkun lati ma so eso.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Yóò dàbí igi tí a gbìn sí ipadò tí ó ta gbòǹgbò rẹ̀ ká etí odò kò sí ìbẹ̀rù fún-un nígbà ooru, gbogbo ìgbà ni èwe rẹ̀ máa ń tutù kò sí ìjáyà fún-un ní ọdún ọ̀dá bẹ́ẹ̀ ni kò ní dẹ́kun láti máa so èso.”