Jeremiah 18:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, sọ fún àwọn ará Juda ati àwọn tí wọn ń gbé Jerusalẹmu pé, èmi OLUWA ní, mò ń pète ibi kan si yín, mo sì ń pinnu rẹ̀ lọ́wọ́ báyìí, kí olukuluku yín yipada kúrò ninu ibi tí ó ń ṣe; kí ẹ sì tún ìwà ati ìṣe yín ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nisisiyi, sa sọ fun awọn enia Juda, ati fun awọn olugbe Jerusalemu wipe, Bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi npete ibi si nyin, emi si nṣe ipinnu kan si nyin, si yipada, olukuluku kuro ninu ọ̀na buburu rẹ̀, ki ẹ si tun ọ̀na ati iṣe nyin ṣe rere.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ǹjẹ́ nísìnsìnyìí, sọ fún àwọn ènìyàn Júdà àti àwọn olúgbé Jérúsálẹ́mù wí pé, ‘Báyìí ní OLÚWA wí: Wò ó! Èmi ń gbérò ibi sí yin, èmi sì ń ṣe ìpinnu kan lórí yín. Nítorí náà ẹ yípadà kúrò lọ́nà búburú yín kí olúkúlúkù yín sì tún ọ̀nà àti ìṣe rè ṣe.’