Jeremiah 18:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn àwọn eniyan mi ti gbàgbé mi, wọ́n ń sun turari sí oriṣa èké. Wọ́n ti kọsẹ̀ ní ojú ọ̀nà àtijọ́ tí wọn ń tọ̀, wọ́n ti yà sí ọ̀nà ojúgbó tí kì í ṣe ojú ọ̀nà tààrà.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe awọn enia mi gbàgbe mi, nwọn ti sun turari fun ohun asan, nwọn si ti mu ki nwọn ki o ṣubu loju ọ̀na wọn, ni ipa igbãni; lati rìn ni ipa ti a kò tẹ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Síbẹ̀ ni àwọn ènìyàn mi ti gbàgbé mi, wọ́n sun tùràrí fún òrìṣà aṣán tí ó mú wọn kọsẹ̀ ní ọ̀nà wọn àti ọ̀nà wọn àtijọ́. Wọ́n mú wọn rìn ní ọ̀nà àtijọ́ àti ní ojú tí a kò kọ́