Jeremiah 18:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé ibi ni eniyan fi í san rere? Sibẹ wọ́n ti wa kòtò sílẹ̀ fún mi. Ranti bí mo ti dúró níwájú rẹ tí mo sọ ọ̀rọ̀ wọn ní rere, kí o baà lè yí ibinu rẹ pada lórí wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
A ha le fi ibi san rere? nitori nwọn ti wà iho fun ẹmi mi. Ranti pe emi ti duro niwaju rẹ lati sọ ohun rere nipa ti wọn, ati lati yi ibinu rẹ kuro lọdọ wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣe kí a fi rere san búburú? Síbẹ̀ wọ́n ti gbẹ́ kòtò fún mi, rántí pé mo dúró níwájú rẹ, mo sì sọ̀rọ̀ ní torí wọn, láti yí ìbínú rẹ kúrò lọ́dọ̀ wọn.