Jeremiah 18:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà ìyàn ni kí ó pa àwọn ọmọ wọn, kí ogun pa wọ́n, kí àwọn aya wọn di aláìlọ́mọ ati opó, kí àjàkálẹ̀ àrùn pa àwọn ọmọkunrin wọn, kí idà ọ̀tá sì pa àwọn ọ̀dọ̀ wọn lójú ogun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina, fi awọn ọmọ wọn fun ìyan, ki o si fi idà pa wọn, jẹ ki aya wọn ki o di alailọmọ ati opó: ki a si fi ìka pa awọn ọkunrin wọn, jẹ ki a fi idà pa awọn ọdọmọde wọn li ogun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, jẹ́ kí ìyàn mú ọmọ wọn jọ̀wọ́ wọn fún ọwọ́ idà jẹ́ kí ìyàwó wọn aláìlọ́mọ àti opó jẹ́ kí a pa àwọn ọkùnrin wọn kí a sì fi idà pa àwọn ọdọ́mọkùnrin wọn lójú ogun.