Jeremiah 18:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA, gbogbo àbá tí wọn ń dá ni o mọ̀, o mọ gbogbo ète tí wọn ń pa láti pa mí. Má dárí ìwà ibi wọn jì wọ́n, má sì pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ níwájú rẹ. Jẹ́ kí wọn ṣubú níwájú rẹ, nígbà tí inú bá ń bí ọ ni kí o bá wọn wí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ mọ̀ gbogbo igbimọ wọn si mi lati pa mi, máṣe bò ẹbi wọn mọlẹ, bẹ̃ni ki iwọ máṣe pa ẹṣẹ wọn rẹ́ kuro niwaju rẹ, jẹ ki nwọn ki o ṣubu niwaju rẹ, bẹ̃ni ki iwọ ki o ṣe si wọn ni ọjọ ibinu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n ìwọ OLÚWA mọ gbogbo ète wọn láti pa mí, má ṣe fojú fò ibi wọn tàbí pa ẹ̀ṣẹ̀ wọn rẹ́ kúrò lójú rẹ. Jẹ́ kí a mú wọn kúrò níwájú rẹ bá wọn jà nígbà ìbínú rẹ.