Jeremiah 19:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
kí n sì sọ fún wọn pé, OLUWA àwọn ọmọ ogun ní, “Bí ẹni fọ́ ìkòkò amọ̀ ni n óo ṣe fọ́ àwọn eniyan yìí ati ìlú yìí, kò sì ní ní àtúnṣe mọ́. Ní Tofeti ni wọn yóo máa sin òkú sí nígbà tí wọn kò bá rí ààyè sin òkú sí mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Bẹ̃ gẹgẹ li emi o fọ enia yi ati ilu yi, bi a ti ifọ ohun-èlo amọkoko, ti ẹnikan kò le tun ṣe mọ, nwọn o si sin wọn ni Tofeti, nitoriti aye kò si lati sinkú.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o sì sọ fún wọn pé, ‘Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun wí. Èmi a fọ́ orílẹ̀ èdè yìí àti ìlú yìí gẹ́gẹ́ bí ìkòkò amọ̀ yìí ṣe fọ́ tí kò sì ní sí àtúnṣe. Wọn a sì sin àwọn òkú sí Tófẹ́tì títí tí kò fi ní sí àyè mọ́.