Jeremiah 19:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ilé Jerusalẹmu ati àwọn ààfin ọba Juda, gbogbo ilé tí wọn ń sun turari sí àwọn ogun ọ̀run lórí òrùlé wọn, tí wọn sì ti rú ẹbọ ohun mímu sí àwọn oriṣa mìíràn, gbogbo wọn ni yóo di aláìmọ́ bíi Tofeti.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gbogbo ile Jerusalemu ati ile awọn ọba Juda ni a o sọ di alaimọ́ bi Tofeti, gbogbo ile wọnni, lori orule eyiti a ti sun turari fun ogun ọrun, ti a si ru ẹbọ mimu fun ọlọrun miran.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àwọn ilé tí ó wà ní Jérúsálẹ́mù àti ti Ọba ìlú Júdà ni a ó sọ di àìmọ́ gẹ́gẹ́ bí ti ibí yìí ní Tófẹ́tì gbogbo ilé tí wọ́n ti ń sun tùràrí ni orí àjà sí gbogbo ènìyàn tí ó sì ń da ọtí gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí Ọlọ́run mìíràn.’ ”