Jeremiah 19:15 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní, ‘N óo mú kí ibi tí mo ti kéde rẹ̀ dé bá ìlú yìí ati àwọn ìlú tí wọn yí i ká, nítorí wọ́n ti ṣe oríkunkun, wọn kò sì gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi; Sa wò o, emi o mu wá sori ilu yi, ati sori ileto rẹ̀ gbogbo ibi ti mo ti sọ si i, nitori ti nwọn ti wà ọrun kì, ki nwọn ki o má bà gbọ́ ọ̀rọ mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọ́run Ísíẹ́lì wí: ‘Tẹ́tí sílẹ̀! Èmi yóò mú ìdààmú tí mo ti sọ àṣọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ bá ìlú yìí àti ìgbéríko tí ó yí i ká, nítorí ọlọ́rùn líle ni wọ́n, wọn kò si ní fẹ́ fetí sí ọ̀rọ̀ mi.’ ”