Jeremiah 19:3 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ OLUWA, ẹ̀yin ọba Juda ati ẹ̀yin tí ẹ̀ ń gbé Jerusalẹmu, OLUWA àwọn ọmọ ogun, Ọlọrun Israẹli ní òun óo mú ibi kan wá sórí ilẹ̀ yìí, híhó ni etí gbogbo àwọn tí wọn bá gbọ́ nípa rẹ̀ yóo máa hó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki o si wipe, Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ọba Juda, ati olugbe Jerusalemu; Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun, Ọlọrun Israeli, wi: sa wò o, emi o mu ibi wá sihin yi, eyiti eti gbogbo awọn ti o ba gbọ́ ọ, yio ho.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí o sì wí pé ‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ẹ̀yin Ọba àwọn Júdà àti ẹ̀yin ará Jérúsálẹ́mù. Èyí ni ohun tí OLÚWA àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ. Dẹtí sí mi! Èmi yóò mú ìparun wá síbí, etí gbogbo wọn tó bá gbọ́ ọ yóò hó yaya.