Jeremiah 19:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé àwọn eniyan wọnyi ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n ti sọ ibí di aláìmọ́ pẹlu turari tí wọn ń sun sí àwọn oriṣa tí àwọn, ati àwọn baba wọn, ati àwọn ọba Juda kò mọ̀ rí. Wọ́n ti pa àwọn aláìṣẹ̀ sí gbogbo ibí yìí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori nwọn ti kọ̀ mi silẹ, nwọn ti sọ ihín yi di iyapa, nwọn si ti sun turari ninu rẹ̀ fun awọn ọlọrun miran, eyiti awọn, tabi awọn baba wọn kò mọ̀ ri, tabi awọn ọba Juda, nwọn si ti fi ẹ̀jẹ alaiṣẹ kún ibi yi;
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí wọ́n ti gbàgbé mi, wọ́n sì ti sọ ibí di ilé fún òrìṣà àjòjì; wọ́n ti sun ẹbọ nínú rẹ̀ fún òrìṣà tí àwọn baba wọn tàbí tí Ọba Júdà kò mọ̀ rí, wọ́n ti fi ẹ̀jẹ̀ aláìsẹ̀ kún ilẹ̀ yìí.