Jeremiah 19:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n kọ́ pẹpẹ oriṣa Baali, wọ́n sì ń fi àwọn ọmọkunrin wọn rú ẹbọ sísun sí i. N kò pàṣẹ fún wọn pé kí wọn máa ṣe bẹ́ẹ̀, n kò fún wọn ní irú ìlànà bẹ́ẹ̀; ohun tí ó jọ bẹ́ẹ̀ kò tilẹ̀ wá sí mi lọ́kàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn ti kọ́ ibi giga fun Baali pẹlu, lati fi iná sun ọmọkunrin wọn, bi ẹbọ-ọrẹ sisun fun Baali, eyiti emi kò pa laṣẹ lati ṣe, ti emi kò si sọ, tabi ti kò si ru soke ninu mi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n ti kọ́ ibi gíga fún Báálì láti sun ọmọkùnrin wọn gẹ́gẹ́ bí ohun ẹbọ sí Báálì. Nǹkan ni èmi kò pa láṣẹ tàbí dárúkọ tí kò sì wá láti inú ọkàn mi.