Jeremiah 19:9 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
N óo mú kí wọn máa pa ọmọ wọn ọkunrin ati obinrin jẹ. Olukuluku yóo máa pa aládùúgbò rẹ̀ jẹ nítorí ìdààmú tí àwọn ọ̀tá wọn, ati àwọn tí ń wá ẹ̀mí wọn yóo kó bá wọn, nígbà tí ogun bá dótì wọ́n.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi o si mu ki nwọn ki o jẹ ẹran-ara awọn ọmọkunrin wọn, ati ẹran-ara awọn ọmọbinrin wọn, ati ẹnikini wọn yio jẹ ẹran-ara ẹnikẹji ni igba idoti ati ihamọ, ti awọn ọta wọn, ati awọn ti o nwá ẹmi wọn yio ha wọn mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò mú kí wọn jẹ ẹran ara ọmọ wọn ọkùnrin àti obìnrin, wọn yóò sì jẹ ẹran ara wọn lásìkò ìparun wọn láti ọwọ́ ọ̀tá wọn, tí ó ń wá ẹ̀mí wọn.’