Jeremiah 2:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ìwà burúkú yín yóo fìyà jẹ yín, ìpadà sẹ́yìn yín yóo sì kọ yín lọ́gbọ́n. Kí ó da yín lójú pé, nǹkan burúkú ni, ìgbẹ̀yìn rẹ̀ kò sì ní dùn, pé ẹ fi èmi OLUWA Ọlọrun yín sílẹ̀; ìbẹ̀rù mi kò sí ninu yín. Èmi, OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ni mo sọ bẹ́ẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ìwa-buburu rẹ ni yio kọ́ ọ, ipadasẹhin rẹ ni yio si ba ọ wi: mọ̀, ki iwọ si ri i pe, ohun buburu ati kikoro ni, pe, iwọ ti kò Oluwa Ọlọrun rẹ, ati pe ìbẹru mi kò si si niwaju rẹ; li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Iṣẹ́ búburú yín yóò fìyà jẹ yín Ìpàdàṣẹ́yìn rẹ yóò sì bá ọ wí mọ̀ kí o sì ríi wí pé ibi àti ohun búburú yóò sì jẹ́ tìrẹ nígbà tí o ti kọ Ọlọ́run ọmọ ogun sílẹ̀, ẹ kò sì ní ìbẹ̀rù fún mi,” ni OLÚWA Ọlọ́run Àwọn ọmọ ogun wí.