Jeremiah 2:20 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA wí pé, “Nítorí pé ó ti pẹ́ tí ẹ ti bọ́ àjàgà yín, tí ẹ sì ti tú ìdè yín; tí ẹ sọ pé, ẹ kò ní sìn mí. Ẹ̀ ń lọ káàkiri lórí gbogbo òkè, ati lábẹ́ gbogbo igi tútù; ẹ̀ ń foríbalẹ̀, ẹ̀ ń ṣe bíi panṣaga.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori ni igba atijọ iwọ ti ṣẹ́ ajaga ọrun rẹ, iwọ si já idè rẹ; iwọ si wipe, Emi kì o sìn, nitori lori oke giga gbogbo, ati labẹ igi tutu gbogbo ni iwọ nṣe panṣaga.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà àtijọ́, o ti fọ́ àjàgà rẹ sọnù, ìwọ sì já ìdè rẹ ìwọ wí pé, ‘Èmi kì yóò sìn ọ́!’ Lóòtọ́, lórí gbogbo òkè gíga ni àti lábẹ́ igi tí ó tàn kálẹ̀ ni ìwọ dùbúlẹ̀ sí gẹ́gẹ́ bí panṣágà.