Jeremiah 2:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Báwo ní ẹ ṣe lè wí pé ẹ kì í ṣe aláìmọ́; ati pé ẹ kò tẹ̀lé àwọn oriṣa Baali? Ẹ wo irú ìwà tí ẹ hù ninu àfonífojì, kí ẹ ranti gbogbo ibi tí ẹ ṣe bí ọmọ ràkúnmí tí ń lọ, tí ń bọ̀; tí ń tọ ipa ọ̀nà ara rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bawo li o ṣe wipe, emi kò ṣe alaimọ́, emi kò tọpa Baalimu? wò ọ̀na rẹ li afonifoji, mọ̀ ohun ti iwọ ti ṣe, iwọ dabi abo ibakasiẹ ayasẹ̀ ti nrin ọ̀na rẹ̀ ka.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Báwo ni o ṣe le lọ sọ pé, ‘Èmi kò ṣe aláìmọ́; Èmi kò ṣáà tẹ̀lé àwọn Báálì’? Wo bí o ṣe hùwà ní àfonífojì; wo ohun tí o ṣe. Ìwọ jẹ́ abo ìbákasíẹ̀ tí ń sá sí ìhín sọ́hùn ún.