Jeremiah 2:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ dàbíi Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́, tí aṣálẹ̀ ti mọ́ lára, tí ń ṣí imú kiri, nígbà tí ó ń wa akọ tí yóo gùn ún. Ta ló lè dá a dúró? Kí akọ tí ó bá ń wá a má wulẹ̀ ṣe ara rẹ̀ ní wahala, nítorí yóo yọjú nígbà tí àkókò gígùn rẹ̀ bá tó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Kẹtẹkẹtẹ igbẹ ti ima gbe aginju, ninu ifẹ ọkàn rẹ̀ ti nfa ẹfufu, li akoko rẹ̀, tani le yi i pada? gbogbo awọn ti nwá a kiri kì yio da ara wọn li agara, nwọn o ri i li oṣu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ìgbẹ́ tí ń gbé ihà tí ń fa ẹ̀fúùfù nínú ìfẹ́ inú rẹ̀ ta ni ó le è mu dúró ní àkókò rẹ̀? Kí gbogbo àwọn ọkùnrin tí í lé e má ṣe dára wọn lágara nítorí wọn ó ò rí ní àkókò oṣù rẹ̀.