Jeremiah 2:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
OLUWA ní, “Bí ojú tíí ti olè nígbà tí ọwọ́ bá tẹ̀ ẹ́, bẹ́ẹ̀ ni ojú yóo tì yín, ẹ̀yin ọmọ Israẹli. Àtẹ̀yin ati àwọn ọba yín, ati àwọn ìjòyè yín, ati àwọn alufaa yín, ati àwọn wolii yín;
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Gẹgẹ bi oju ti itì ole nigbati a ba mu u, bẹ̃li oju tì ile Israeli; awọn ọba wọn, ijoye wọn, alufa wọn, ati woli wọn pẹlu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Gẹ́gẹ́ bí a ṣe ń dójú ti olè nígbà tí a bá mú u, bẹ́ẹ̀ náà ni ilé Ísírẹ́lì yóò gba, àwọn ìjòyè wọn, àwọn àlùfáà àti wòlíì wọn pẹ̀lú.