Jeremiah 2:27 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wí fún igi pé igi ni baba yín, tí ẹ sì ń sọ fún òkúta pé òkúta ni ó bi yín; nítorí pé dípò kí ẹ kọjú sí ọ̀dọ̀ mi, ẹ̀yìn ni ẹ kọ sí mi. Ṣugbọn nígbà tí ìṣòro dé ba yín, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí kígbe pè mí pé kí n dìde, kí n gbà yín là.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ti nwọn wi fun igi pe, Iwọ ni baba mi; ati fun okuta pe, iwọ li o bi mi. Nitori nwọn ti yi ẹ̀hìn wọn pada si mi kì iṣe iwaju wọn: ṣugbọn ni igba ipọnju wọn, nwọn o wipe, Dide, ki o gbani.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn sọ fún igi pé, ‘Ìwọ ni bàbá mi,’ àti sí òkúta wí pé, ‘Ìwọ ni ó bí mi,’ wọ́n ti kọ ẹ̀yìn wọn sí mi, wọn kò kọ ojú sí mi ṣíbẹ̀ nígbà tí wọ́n bá wà nínú ìṣòro, wọn yóò wí pé, ‘Wá kí o sì gbà wá!’