Jeremiah 2:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ṣugbọn níbo ni àwọn oriṣa yín tí ẹ dá fún ara yín wà? Kí wọn dìde, tí wọ́n bá lè gbà yín ní àkókò ìṣòro yín! Ṣebí bí ìlú yín ti pọ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni àwọn oriṣa yín náà pọ̀ tó, ẹ̀yin ará Juda.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Njẹ nibo li awọn ọlọrun rẹ wà, ti iwọ ti da fun ara rẹ? jẹ ki nwọn ki o dide, bi nwọn ba le gba ọ nigba ipọnju rẹ, nitori bi iye ilu rẹ, bẹ̃li ọlọrun rẹ, iwọ Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Níbo wá ni àwọn Ọlọ́run (kékeré) tí ẹ ṣe fúnra yín há a wà? Jẹ́ kí wọn wá kí wọn sì gbà yín nígbà tí ẹ bá wà nínú ìṣòro! Nítorí pé ẹ̀yin ní àwọn Ọlọ́run púpọ̀, gẹ́gẹ́ bí ẹ ṣe ni àwọn ìlú, ìwọ Júdà.