Jeremiah 2:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo na àwọn ọmọ yín lásán ni, wọn kò gba ẹ̀kọ́. Ẹ̀yin gan-an ni ẹ fi idà pa àwọn wolii yín ní àparun, bíi kinniun tí ń pa ẹran kiri.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lasan ni mo lù ọmọ nyin, nwọn kò gbà ibawi, idà ẹnyin tikara nyin li o pa awọn woli bi kiniun apanirun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nínú aṣán mo fìyà jẹ àwọn ènìyàn yín, wọn kò sì gba ìbáwí, idà yín ti pa àwọn wòlíì yín run, gẹ́gẹ́ bí kìnnìún tí ń bú ramúramù.