Jeremiah 2:31 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ gbọ́ ohun tí èmi, OLUWA ń sọ. Ṣé aṣálẹ̀ ni mo jẹ́ fún Israẹli; tabi mo ti di ilẹ̀ òkùnkùn biribiri? Kí ló dé tí ẹ̀yin eniyan mi fí ń sọ pé, ‘A ti di òmìnira, a lè máa káàkiri; a kò ní wá sí ọ̀dọ̀ rẹ mọ́?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Iran enia yi, ẹ kiyesi ọ̀rọ Oluwa. Emi ha ti di aginju si Israeli bi? tabi ilẹ okunkun biribiri, ẽṣe ti enia mi wipe, awa nrin kakiri, awa kì yio tọ̀ ọ wá mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ẹ̀yin ìran yìí, ẹ kíyèsí ọ̀rọ̀ OLÚWA: “Àbí ilẹ̀ ńlá olókùnkùn kí ló dé tí àwọn ènìyàn mi ṣe sọ wí pé, ‘A ní àǹfààní láti máa rìn kiri? A kò sì ní wá sọ́dọ̀ rẹ mọ́?’