Jeremiah 2:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní: “Nǹkan burúkú wo ni àwọn baba ńlá yín ní mo fi ṣe àwọn, tí wọ́n jìnnà sí mi; tí wọ́n fi bẹ̀rẹ̀ síí bọ oriṣa lásánlàsàn, tí àwọn pàápàá sì fi di eniyan lásán?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi: Aiṣedede wo li awọn baba nyin ri lọwọ mi ti nwọn lọ jina kuro lọdọ mi, ti nwọn si tẹle asan, ti nwọn si di enia asan?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA wí: “Irú àwọn àìṣedédé wo ni baba yín rí nínú mi? Tí wọ́n fi jìnnà sími? Wọ́n tẹ̀lé àwọn òrìṣà tí kò jámọ́ nǹkan kan àwọn fúnra wọn sì jẹ́ ènìyàn yẹpẹrẹ.