Jeremiah 2:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọn kò bèèrè pé, Níbo ni OLUWA wà, ẹni tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti, tí ó sìn wá la aṣálẹ̀ já, ilẹ̀ aṣálẹ̀ tí ó kún fún ọ̀gbun, ilẹ̀ ọ̀dá ati òkùnkùn biribiri, ilẹ̀ tí eniyan kìí là kọjá, tí ẹnikẹ́ni kì í gbé?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃ni nwọn kò si wipe, nibo li Oluwa wà? ti o mu wa goke lati ilẹ Egipti wá, ti o mu wa rìn ninu iju, ninu ilẹ pẹtẹlẹ ati ihò, ninu ilẹ gbigbẹ ati ojiji ikú, ninu ilẹ ti enia kò là kọja, ati nibiti enia kò tẹdo si.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọn kò béèrè, ‘Níbo ni OLÚWA wà tí ó mú wọn, jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì, tí ó mú wa la ihà já, tí ó mu wọn la àárin àwọn aṣálẹ̀ àti òkè láàrin ìyàngbẹ ilẹ̀ àti òkùnkùn wá ilẹ̀ ibi tí ẹnikẹ́ni kò ti rìnrìn-àjò, tí ẹníkẹ́ni kò sì gbé?’