Jeremiah 2:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Mo mu yín wá sí ilẹ̀ tí ó lọ́ràá, pé kí ẹ máa gbádùn èso rẹ̀ ati àwọn nǹkan dáradára tí wọ́n wà ninu rẹ̀, ṣugbọn nígbà tí ẹ dé inú rẹ̀, ẹ sọ ilẹ̀ mi di aláìmọ́, ẹ sì sọ ogún mi di ohun ìríra.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi si mu nyin wá si ilẹ ọgba-eso, lati jẹ eso rẹ̀ ati ire rẹ̀; ṣugbọn ẹnyin wọ inu rẹ̀, ẹ si ba ilẹ mi jẹ, ẹ si sọ ogún mi di ohun irira:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo mú yín wá sí ilẹ̀ ọlọ́ràá láti máa jẹ èso ibẹ̀ àti ọrọ̀ rẹ̀, ẹ̀yin sì wá, ẹ sì ba ilẹ̀ náà jẹ́, ẹ sì mú àwọn ohun ogún mi di ohun ìríra.