Jeremiah 2:8 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn alufaa kò bèèrè pé, ‘OLUWA dà?’ Àwọn tí wọn ń ṣe àmójútó òfin kò mọ̀ mí, àwọn olórí ń dìtẹ̀ sí mi, àwọn wolii ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ ní orúkọ oriṣa Baali, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn oriṣa lásánlàsàn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn alufa kò wipe, Nibo li Oluwa wà? ati awọn ti o mu ofin lọwọ kò mọ̀ mi: awọn oluṣọ si ṣẹ̀ si mi, ati awọn woli sọ asọtẹlẹ nipa Baali, nwọn si tẹle ohun ti kò lerè.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Àlùfáà kò bèèrè wí pé níbo ni OLÚWA wà? Àwọn tí ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú òfin kò si mọ̀ mí, àwọn olórí wọn sì gbógun sí mi, àwọn wòlíì sì ń sọ tẹ́lẹ̀ nípa òrìṣà báálì, wọ́n sì ń tẹ̀lé àwọn òrìṣà yẹpẹrẹ.