Jeremiah 20:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí mò ń gbọ́ tí ọpọlọpọ ń sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ pé, “Ìpayà wà lọ́tùn-ún lósì, ẹ lọ fẹjọ́ rẹ̀ sùn. Ẹ jẹ́ kí á fẹjọ́ rẹ̀ sùn.” Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń wí, tí wọn sì ń retí ìṣubú mi. Wọ́n ń sọ pé, “Bóyá yóo bọ́ sọ́wọ́ ẹlẹ́tàn, ọwọ́ wa yóo sì tẹ̀ ẹ́; a óo sì gbẹ̀san lára rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoriti mo gbọ́ ẹgan ọ̀pọlọpọ, idãmu niha gbogbo, nwọn wipe: fi sùn, awa o si fi sùn. Gbogbo awọn ọrẹ mi, ati gbogbo awọn ẹgbẹ mi wipe: bọya a o tãn jẹ, awa o si ṣẹgun rẹ̀, a o si gbẹsan wa lara rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Mo gbọ́ sísọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, ìbẹ̀rù ni ibi gbogbo Fi í sùn! Jẹ́ kí a fi sùn! Gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ mi ń dúró kí èmi ṣubú, wọ́n sì ń sọ pé, Bóyá yóò jẹ́ di títàn, nígbà náà ni àwa yóò borí rẹ̀, àwa yóò sì gba ẹ̀san wa lára rẹ̀.”