Jeremiah 20:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA ní, ‘N óo sọ ọ́ di ìpayà fún ara rẹ ati fún gbogbo àwọn tí wọ́n fẹ́ràn rẹ. Àwọn ọ̀tá yóo fi idà pa wọ́n níṣojú rẹ, n óo fi gbogbo ilẹ̀ Juda lé ọba Babiloni lọ́wọ́. Yóo kó wọn ní ìgbèkùn lọ sí Babiloni, yóo sì fi idà pa wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi, sa wò o, emi o fi ọ le idãmu lọwọ, pẹlu gbogbo awọn ọrẹ rẹ, nwọn o ṣubu nipa idà awọn ọta wọn, oju rẹ yio si ri i, emi o si fi gbogbo Juda le ọwọ ọba Babeli, on o si mu wọn lọ ni igbèkun si Babeli, yio si fi idà pa wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí èyí ni ohun tí OLÚWA sọ. Èmi yóò mú ọ di ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀ sí ara rẹ àti sí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ. Ní ojú ara rẹ, ìwọ yóò sì rí tí wọ́n ṣubú nípa idà ọ̀tá wọn. Èmi yóò fi gbogbo àwọn ọ̀tá Júdà lé Ọba Bábílónì lọ́wọ́, òun yóò sì kó wọn lọ sí Bábílónì tàbí kí ó pa wọ́n.