Jeremiah 20:5 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bákan náà, n óo da gbogbo ọrọ̀ ìlú yìí, ati gbogbo èrè iṣẹ́ tí wọ́n ṣe lé àwọn ará Babiloni lọ́wọ́, pẹlu gbogbo nǹkan olówó iyebíye wọn, ati gbogbo ìṣúra àwọn ọba Juda; gbogbo rẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wọn, àwọn ará Babiloni yóo fogun kó, wọn yóo sì rù wọ́n lọ sí Babiloni.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Pẹlupẹlu emi o fi ọrọ̀ ilu yi, pẹlu ẽre rẹ̀ ati ohun iyebiye rẹ̀, ati gbogbo iṣura awọn ọba Juda li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ti yio jẹ wọn ti yio si mu wọn lọ si Babeli.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò jọ̀wọ́ gbogbo ọrọ̀ inú ìlú yìí fún ọ̀ta wọn. Gbogbo ìní wọ́n gbogbo ọlá Ọba Júdà. Wọn yóò sì ru ìkógun lọ sí Bábílónì.