Jeremiah 20:7 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA, o tàn mí jẹ, mo sì gba ẹ̀tàn; o ní agbára jù mí lọ, o sì borí mi. Mo di ẹni ẹ̀sín láti àárọ̀ títí di alẹ́, gbogbo eniyan ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa, iwọ ti fi ọ̀rọ rọ̀ mi, emi si gba rirọ̀! iwọ li agbara jù mi lọ, o si bori mi; emi di ẹni iyọ-ṣuti-si lojojumọ, gbogbo wọn ni ngàn mi!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA, o tàn mí jẹ́, o sì ṣẹ́gun. Mo di ẹni ẹ̀gàn ní gbogbo ọjọ́, gbogbo ènìyàn fi mí ṣẹlẹ́yà.