Jeremiah 21:14 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
N óo jẹ yín níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ yín; èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. N óo dáná sun igbó yín, yóo sì jó gbogbo ohun tí ó wà ní agbègbè yín ní àjórun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi o jẹ nyin niya gẹgẹ bi eso iṣe nyin, li Oluwa wi; emi o si da iná ninu igbo rẹ ki o le jo gbogbo agbegbe rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi yóò jẹ ẹ́ níyà gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ ni OLÚWA wí. Èmi yóò mú kí iná jó ilé rẹ̀; ìyẹn yóò jó gbogbo ohun tí ó wà ní àyíká rẹ.’ ”