Jeremiah 21:2 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
tí ọba Sedekaya ní, “Ẹ sọ fún Jeremaya pé kí ó bá wa ṣe ìwádìí lọ́dọ̀ OLUWA nípa Nebukadinesari, ọba Babiloni, tí ó gbógun tì wá; bóyá OLUWA yóo ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ fún wa, kí Nebukadinesari kó àwọn ọmọ ogun rẹ̀ kúrò ní ilẹ̀ wa.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bère, emi bẹ ọ, lọdọ Oluwa fun wa; nitori Nebukadnessari, ọba Babeli, ṣi ogun tì wa; bọya bi Oluwa yio ba wa lò gẹgẹ bi gbogbo iṣẹ iyanu rẹ̀, ki on ki o le lọ kuro lọdọ wa.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Wádìí lọ́wọ́ OLÚWA fún wa nítorí Nebukadinésárì Ọba Bábílónì ń kọlù wá. Bóyá OLÚWA yóò ṣe ìyanu fún wa gẹ́gẹ́ bí ti àtẹ̀yìnwá, kí ó sì yípadà kúrò lọ́dọ̀ wa.”