Jeremiah 21:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
kí wọ́n sọ fún Sedekaya pé OLUWA Ọlọrun Israẹli ní, “N óo gba àwọn ohun ìjà tí ó wà lọ́wọ́ yín, tí ẹ fi ń bá ọba Babiloni ati àwọn ará Kalidea tí wọn gbógun tì yín lẹ́yìn odi jà, n óo dá wọn pada sí ààrin ìlú, n óo sì dojú wọn kọ yín.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli wi: wõ, emi o yi ihamọra ogun ti o wà ni ọwọ nyin pada, eyiti ẹnyin nfi ba ọba Babeli, ati awọn ara Kaldea jà, ti o dotì nyin lẹhin odi, emi o kó wọn jọ si ãrin ilu yi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Èyí ni OLÚWA, Ọlọ́run Ísírẹ́lì wí: Èmi fẹ́ kọjú idà tí ó wà lọ́wọ́ yín sí yín, èyí tí ẹ̀ ń lò láti bá Ọba àti àwọn ará Bábílónì tí wọ́n wà lẹ́yìn odi jà, Èmi yóò sì kó wọn jọ sínú ìlú yìí.