Jeremiah 21:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Lẹ́yìn náà n óo mú Sedekaya ọba Juda, ati àwọn ìjòyè rẹ̀, ati àwọn tí àjàkálẹ̀ àrùn, ogun, ati ìyàn, bá pa kù ní ìlú yìí, n óo fi wọ́n lé Nebukadinesari, ọba Babiloni lọ́wọ́, òun ati àwọn ọ̀tá tí ń wá ọ̀nà láti pa wọ́n. Ọba Babiloni yóo fi idà pa wọ́n, kò ní ṣàánú wọn, kò sì ní dá ẹnikẹ́ni sí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lẹhin eyi, li Oluwa wi, emi o fi Sedekiah, ọba Juda, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati awọn enia, ati awọn ti o kù ni ilu yi lọwọ ajakalẹ-àrun ati lọwọ idà, ati lọwọ ìyan; emi o fi wọn le Nebukadnessari, ọba Babeli lọwọ, ati le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: yio si fi oju idà pa wọn; kì yio da wọn si, bẹ̃ni kì yio ni iyọ́nu tabi ãnu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
OLÚWA sọ pé lẹ́yìn ìyẹn, èmi yóò fi Sedekáyà Ọba Júdà, àwọn ìjòyè àti gbogbo àwọn tí ó yọ nínú ìṣẹ̀lẹ̀ ogun àti ìyàn lé Ọba Nebukadinésárì àti Bábílónì àti gbogbo ọ̀ta wọn tí ń lépa ẹ̀mí wọn lọ́wọ́. Òun yóò sì fi idà pa wọ́n, kì yóò sì ṣàánú wọn.’