Jeremiah 22:10 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ẹ̀yin ará Juda, ẹ má sọkún nítorí ọba tí ó kú, ẹ má sì dárò rẹ̀. Ọba tí ń lọ sí ìgbèkùn ni kí ẹ sọkún fún, nítorí pé yóo lọ, kò sì ní pada wá mọ́ láti fojú kan ilẹ̀ tí a bí i sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ máṣe sọkun fun okú, bẹ̃ni ki ẹ máṣe pohùnrere rẹ̀, ṣugbọn ẹ sọkun ẹ̀dun fun ẹniti o nlọ, nitori kì yio pada wá mọ, kì yio si ri ilẹ rẹ̀ mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà má ṣe sunkún nítorí Ọba tí ó ti kú tàbí sọ̀fọ̀ fún àdánù rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹ sunkún kíkorò fún ẹni tí a lé kúrò nílùú nítorí kì yóò padà wá mọ́ tàbí fi ojú rí ilẹ̀ tí a ti bí i.