Jeremiah 22:11 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé OLUWA sọ nípa Joahasi, ọba Juda, ọmọ Josaya, tí ó jọba dípò Josaya baba rẹ̀, tí ó sì jáde kúrò ní ibí yìí pé, “Kò ní pada sibẹ mọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi fun Ṣallumu, ọmọ Josiah, ọba Juda, ti o jọba ni ipo Josiah, baba rẹ̀, ti o jade kuro nihin pe, On kì yio pada wá mọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí báyìí ni OLÚWA wí, nípa Ṣálúmù ọmọ Jòsáyà Ọba Júdà tí ó jọba lẹ́yìn baba rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ó jáde kúrò níhìn ín: “Òun kì yóò padà wá mọ́.