Jeremiah 22:13 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹni tí ó ń fi aiṣododo kọ́ ilé rẹ̀ gbé, tí ó ń fi ọ̀nà èrú kọ́ òrùlé rẹ̀. Tí ó mú ọmọ ẹnìkejì rẹ̀ sìn lọ́fẹ̀ẹ́, láìsan owó iṣẹ́ rẹ̀ fún un.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egbe ni fun ẹniti o kọ́ ilẹ rẹ̀, ti kì iṣe nipa ododo, ati iyẹwu rẹ̀, ti kì iṣe nipa ẹ̀tọ́: ti o lò iṣẹ ọwọ aladugbo rẹ̀ lọfẹ, ti kò fi ere iṣẹ rẹ̀ fun u.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ègbé ni fún ẹni tí a kọ́ ààfin rẹ̀ lọ́nà àìsòdodo, àti àwọn yàrá òkè rẹ̀ lọ́nà àìtọ́ tí ó mú kí àwọn ará ìlú rẹ ṣiṣẹ́ lásán láì san owó iṣẹ́ wọn fún wọn.