Jeremiah 22:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà, OLUWA sọ nípa Jehoiakimu, ọba Juda, ọmọ Josaya pé, wọn kò ní dárò rẹ̀, pé, “Ó ṣe, arakunrin mi!” Tabi pé, “Ó ṣe, arabinrin mi!” Wọn kò ní ké pé, “Ó ṣe, oluwa mi!” Tabi pé, “Ó ṣe! Áà! Kabiyesi!”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina bayi li Oluwa wi nitori Jehoiakimu ọmọ Josiah, ọba Juda, nwọn kì yio ṣọ̀fọ fun u, wipe, Oṣe! arakunrin mi! tabi Oṣe! arabinrin mi! nwọn kì o ṣọ̀fọ fun u pe, Oṣe, oluwa! tabi Oṣe, ọlọla!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà báyìí ni OLÚWA wí, nípa Jehóíákímù ọmọ Jòsáyà, Ọba Júdà: “Wọn kì yóò ṣọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, arákùnrin mi! Ó ṣe, arábìnrin mi!’ Wọn kì yóò sọ̀fọ̀ fún un: wí pé, ‘Ó ṣe, olúwa tàbí ó ṣe kábíyèsí!’