Jeremiah 22:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Gbọ́ ohun tí OLUWA sọ, ìwọ ọba Juda, tí o jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi, ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ ati àwọn eniyan rẹ, tí wọn ń gba àwọn ẹnubodè wọnyi wọlé:
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wipe, Gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ọba Juda, ti o joko ni itẹ Dafidi, iwọ, ati awọn iranṣẹ rẹ, ati awọn enia rẹ ti o wọle ẹnu-bode wọnyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
‘Gbọ́ ọ̀rọ̀ OLÚWA ìwọ Ọba Júdà, tí ó jókòó ní Ìtẹ́ Dáfídì, ìwọ, àwọn ènìyàn rẹ àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ, tí ó wọlé láti ẹnu ibodè wọ̀nyí.