Jeremiah 22:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA bá yín sọ̀rọ̀ nígbà tí nǹkan ń dára fun yín, ṣugbọn ẹ sọ pé ẹ kò ní gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ tí ń ṣe láti kékeré yín, ẹ kì í gbọ́rọ̀ sí OLUWA lẹ́nu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Emi ti ba ọ sọ̀rọ ni ìgba ire rẹ; iwọ wipe, emi kì yio gbọ́. Eyi ni ìwa rẹ lati igba ewe rẹ wá, ti iwọ kò si gba ohùn mi gbọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Èmi ti kìlọ̀ fún ọ nígbà tí o rò pé kò séwu, ṣùgbọ́n o sọ pé, ‘Èmi kì yóò fetísílẹ̀!’ Èyí ni iṣẹ́ rẹ láti ìgbà èwe rẹ, ìwọ kò fìgbà kan gba ohùn mi gbọ́.