Jeremiah 22:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Afẹ́fẹ́ yóo fẹ́ gbogbo àwọn olórí yín lọ, àwọn olólùfẹ́ yín yóo lọ sí ìgbèkùn. Ojú yóo wá tì yín, ẹ óo sì di ẹni ẹ̀tẹ́, nítorí gbogbo ibi tí ẹ̀ ń ṣe.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹfũfu yio fẹ gbogbo oluṣọ-agutan rẹ lọ, ati awọn olufẹ rẹ yio lọ si ìgbekun: nitõtọ, ni wakati na ni oju yio tì ọ, iwọ o si dãmu nitori gbogbo buburu rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ̀fúùfù yóò lé gbogbo àwọn olùṣọ́-àgùntàn rẹ̀ lọ, gbogbo àwọn olùfẹ́ rẹ yóò lọ sí ìgbékùn, nígbà náà ni a ó kẹ́gàn rẹ, ojú yóò tì ọ́ nítorí gbogbo ìwà búburú rẹ.