Jeremiah 22:28 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣé àfọ́kù ìkòkò tí ẹnikẹ́ni kò kà kún ni Jehoiakini? Àbí o ti di ohun èlò àlòpatì? Kí ló dé tí òun ati àwọn ọmọ rẹ̀ fi di ẹni tí a kó lẹ́rú lọ sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀ rí?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ọkunrin yi, Koniah, ohun-èlo ẹlẹgan, fifọ ha ni bi? o ha dabi ohun-èlo ti kò ni ẹwà lara? ẽṣe ti a tì wọn jade, on, ati iru-ọmọ rẹ̀, ti a si le wọn jade si ilẹ ti nwọn kò mọ̀?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ǹjẹ́ Jéhóíákínì ẹni ẹ̀gàn yàtọ̀ sí ìkòkò òfìfo, ohun èlò tí ẹnìkan kò fẹ́? Èéṣe tí a fi òun àti àwọn ọmọ rẹ̀ sókè sí ilẹ̀ tí wọn kò mọ̀.