Jeremiah 22:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó ní, “Ẹ kọ orúkọ ọkunrin yìí sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ, ẹni tí kò ní ṣe rere kan ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí pé kò sí ọ̀kankan ninu àwọn ọmọ rẹ̀ tí yóo rọ́pò rẹ̀ lórí ìtẹ́ Dafidi, Ìdílé rẹ̀ kò sì ní jọba mọ ní Juda.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bayi li Oluwa wi, Ẹ kọwe pe, ọkunrin yi alailọmọ ni, ẹniti kì yio ri rere li ọjọ aiye rẹ̀: nitori ọkan ninu iru-ọmọ rẹ̀ kì yio ri rere, ti yio fi joko lori itẹ Dafidi, ti yio si fi tun jọba lori Juda.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Báyìí ni OLÚWA wí: “Kọ àkọsílẹ̀ ọkùnrin yìí sínú ìwé gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́mọ, ẹni tí kì yóò ṣe rere ní ọjọ́ ayé rẹ̀; nítorí ọ̀kan nínú irú ọmọ rẹ̀ kì yóò ṣe rere, èyíkéyìí wọn kì yóò jókòó lórí ìtẹ́ Dáfídì tàbí jọba ní Júdà mọ́.”