Jeremiah 22:4 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí pé bí ẹ bá fi tọkàntọkàn fetí sí ọ̀rọ̀ mi, àwọn ọba yóo máa wọlé, wọn yóo sì máa jókòó lórí ìtẹ́ Dafidi. Wọn yóo máa gun ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun àtàwọn, ati àwọn ìjòyè wọn, ati àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bi ẹnyin ba ṣe nkan yi nitõtọ, nigbana ni awọn ọba yio wọle ẹnu-bode ilu yi, ti nwọn o joko lori itẹ Dafidi, ti yio gun kẹ̀kẹ ati ẹṣin, on, ati awọn iranṣẹ rẹ̀, ati enia rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí bí ẹ̀yin bá tẹ̀lé àṣẹ wọ̀nyí, nígbà náà ni àwọn Ọba inú ààfin láti ẹnu ọ̀nà, wọn yóò gun kẹ̀kẹ́ àti ẹṣin, àwọn àti ìránṣẹ́ wọn àti àwọn ènìyàn wọn.