Jeremiah 22:6 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
OLUWA sọ nípa ìdílé ọba Juda pé, “Bíi Gileadi ni o dára lójú mi, ati bí orí òkè Lẹbanoni. Ṣugbọn sibẹ, dájúdájú, n óo sọ ọ́ di aṣálẹ̀; o óo sì di ìlú tí ẹnikẹ́ni kò ní gbé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori bayi li Oluwa wi fun ile ọba Juda; Gileadi ni iwọ si mi, ori Lebanoni: sibẹ, lõtọ emi o sọ ọ di aginju, ati ilu ti a kò gbe inu wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí báyìí ni OLÚWA wí, nípa ààfin Ọba Júdà, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé ìwọ dàbí Gílíádì sí mi, gẹ́gẹ́ bí góńgó òkè Lẹ́bánónì, dájúdájú Èmi yóò sọ ọ́ di aṣálẹ̀, àní gẹ́gẹ́ bí ìlú tí a kò gbé inú wọn.