Jeremiah 23:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí náà ọ̀nà wọn yóo dàbí ọ̀nà tí ń yọ̀ ninu òkùnkùn, a óo tì wọ́n sinu rẹ̀, wọn yóo sì ṣubú, nítorí n óo mú kí ibi bá wọn ní ọdún ìjìyà wọn.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ipa-ọ̀na wọn yio jẹ fun wọn bi ibi yiyọ́ li okunkun: a o tì wọn, nwọn o si ṣubu ninu rẹ̀, nitori emi o mu ibi wá sori wọn, ani ọdun ibẹ̀wo wọn, li Oluwa wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí náà, ọ̀nà wọn yóò di yíyọ́, a ó lé wọn jáde sínú òkùnkùn; níbẹ̀ ni wọn yóò ṣubú. Èmi yóò mú ìdààmú wá sórí wọn, ní ọdún tí a jẹ wọ́n níyà,” ni OLÚWA wí.